Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:6 - Yoruba Bible

6 Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:6
16 Iomraidhean Croise  

Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe.


Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ;


Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn.


Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀.


Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani.


àwọn tí wọ́n rí i mú un wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni ati gbogbo ìjọ eniyan.


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.


“Tí ẹnìkan bá kú ninu àgọ́ kan ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ninu àgọ́ náà, ati ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ibẹ̀ yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.


Lẹ́yìn náà yóo mú hisopu, yóo tì í bọ omi náà, yóo sì fi wọ́n àgọ́ náà ati àwọn ohun èlò tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Yóo fi wọ́n ẹni tí ó fọwọ́ kan egungun òkú tabi tí ó fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n pa, tabi ẹni tí ó kú fúnrarẹ̀, tabi ibojì òkú.


lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé,


Mose bá bá OLUWA sọ̀rọ̀ nípa wọn,


“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú.


“Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?”


Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan