Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:16 - Yoruba Bible

16 Ìkùukùu ni lọ́sàn-án, ṣugbọn ní alẹ́, ó dàbí ọ̀wọ̀n iná. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì máa ń rí nígbà gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Bẹ̃li o si ri nigbagbogbo: awọsanma bò o, ati oye iná li oru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:16
13 Iomraidhean Croise  

Ò ń fi ọ̀wọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, o sì ń fi ọ̀wọ̀n iná darí wọn lóru, ò ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n rìn.


nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn.


OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n, ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.


Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán, ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.


Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀.


Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli.


Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.


Iṣẹ́ náà ni pé Ọlọrun wà ninu Kristi, ó ń làjà láàrin aráyé ati ara rẹ̀. Kò ka àwọn ìwà àìṣedéédé wọn sí wọn lọ́rùn. Ó sì ti wá fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́.


Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí.


Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan