Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:13 - Yoruba Bible

13 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ́, tí kò lọ sí ìrìn àjò, ṣugbọn tí kò ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ni a ó yọ kúrò láàrin àwọn eniyan mi, nítorí kò mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLUWA ní àkókò rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:13
24 Iomraidhean Croise  

Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.”


“Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́.


Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà.


Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ”


Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.”


N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”


“Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.


tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.


Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ.


“Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.


Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ.


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.


Nígbà náà ni ọkunrin náà yóo bọ́ ninu ẹ̀bi, ṣugbọn obinrin náà yóo forí ru ẹ̀bi àìdára tí ó ṣe.”


“Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?”


Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.


báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.


tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.


Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan