Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 9:12 - Yoruba Bible

12 Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 9:12
7 Iomraidhean Croise  

Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún.


OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá.


Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀.


Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro.


Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli.


Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí, láti àṣáálẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.”


Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan