Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:8 - Yoruba Bible

8 Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:8
12 Iomraidhean Croise  

“Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù,


Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà.


Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.


“Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.


Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.


“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀.


nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ.


“Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.


“Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.


Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́.


Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan