Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:7 - Yoruba Bible

7 Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:7
24 Iomraidhean Croise  

Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.


Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!


Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.


OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta,


Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu, nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀, òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.


Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ, kí á lè gbà ọ́ là. Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?


N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá.


Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ.


Ẹ sì níláti fọ gbogbo aṣọ yín, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí a fi awọ ṣe, tabi irun ewúrẹ́, tabi igi.”


Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.


Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.


Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara,


Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì.


Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi,


Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan