Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:4 - Yoruba Bible

4 Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà, láti ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ títí dé ìtànná orí rẹ̀. Mose ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí OLUWA fi hàn án.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Iṣẹ ọpá-fitila na yi si jẹ̀ ti wurà lilù; titi dé isalẹ rẹ̀, titi dé itanna rẹ̀, o jẹ́ iṣẹ lulù: gẹgẹ bi apẹrẹ ti OLUWA fihàn Mose, bẹ̃li o ṣe ọpá-fitila na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí: A ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìsàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànì tí Olúwa fihan Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:4
11 Iomraidhean Croise  

Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà.


Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.


Bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, ni kí o ṣe kọ́ àgọ́ náà.


Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà,


Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.”


Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan