Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:21 - Yoruba Bible

21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:21
10 Iomraidhean Croise  

OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta,


Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.


Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, yóo wẹ ara rẹ̀ pẹlu omi ìwẹ̀nùmọ́, yóo sì di mímọ́. Kò ní di mímọ́ bí kò bá wẹ ara rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje.


Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́.


“Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi,


Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.


Mose ati Aaroni ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí wọ́n ṣe.


Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli ṣe fun àwọn ọmọ Lefi, ni wọ́n ṣe.


Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan