Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:2 - Yoruba Bible

2 kí ó sọ fún Aaroni pé, nígbà tí Aaroni bá tan fìtílà mejeeje, kí ó gbé wọn sórí ọ̀pá fìtílà kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju ọ̀pá náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Bá Aaroni sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé. ‘Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:2
19 Iomraidhean Croise  

Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi, òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.


Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀, a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.


Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju.


Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà.


Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe, ati àwọn fìtílà orí rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati òróró ìtànná rẹ̀.


Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.


Aaroni yóo sì máa ṣe ìtọ́jú àwọn àtùpà tí wọ́n wà lórí ọ̀pá fìtílà wúrà, kí wọ́n lè máa wà ní títàn níwájú OLUWA nígbà gbogbo.


Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.


“Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́.


Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé.


A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín.


Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje.


Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.


Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan