Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:16 - Yoruba Bible

16 Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:16
6 Iomraidhean Croise  

“Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.”


“Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi,


nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.”


“Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli, ati ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn wọn. Àwọn ọmọ Lefi yóo sì jẹ́ tèmi. Èmi ni OLUWA.


“Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un.


Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan