Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:12 - Yoruba Bible

12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Lefi yóo gbé ọwọ́ wọn lé àwọn akọ mààlúù náà lórí. O óo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, o óo sì fi ikeji rú ẹbọ sísun sí OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:12
25 Iomraidhean Croise  

“Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí.


Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.


ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun.


“Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.


Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀.


Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀.


Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀.


Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n.


Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í.


Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA.


“Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.


Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí.


Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.


Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.


Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.


Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”


pẹlu àwọn ọrẹ tí ó fẹ́ fún OLUWA: ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ sísun; abo ọ̀dọ́ aguntan, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ alaafia,


“Alufaa yóo sì kó àwọn nǹkan wọnyi wá siwaju OLUWA, yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun rẹ̀.


“Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli; wọn óo sì máa ṣe iranṣẹ fún Aaroni alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀.


Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan