Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:9 - Yoruba Bible

9 Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:9
9 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA.


Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà;


Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú.


Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà.


Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”


Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un.


Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”


Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àpótí majẹmu ati tabili, ọ̀pá fìtílà ati àwọn pẹpẹ, ati àwọn ohun èlò ní ibi mímọ́, tí àwọn alufaa máa ń lò fún iṣẹ́ ìsìn; ati aṣọ ìbòjú, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ohun èlò wọnyi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan