Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:89 - Yoruba Bible

89 Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, ó gbọ́ ohùn kan tí ń bá a sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, láàrin àwọn kerubu mejeeji. Ẹni náà bá Mose sọ̀rọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

89 Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

89 Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:89
15 Iomraidhean Croise  

Wọ́n fi igi olifi gbẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́ meji tí wọn ń pè ní Kerubu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá, wọ́n kó wọn sinu Ibi-Mímọ́-Jùlọ náà.


Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́


OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì; ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.


Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀.


Mose kò sì lè wọ inú rẹ̀ nítorí ìkùukùu tí ó wà lórí rẹ̀, ati pé ògo OLUWA kún inú rẹ̀.


OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní,


Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,


N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà.


Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.


Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.


Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan