Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:88 - Yoruba Bible

88 Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

88 Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

88 Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:88
5 Iomraidhean Croise  

Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá rẹ̀, gbogbo ọ̀rá tí ó wà ní ìrù rẹ̀ títí dé ibi egungun ẹ̀yìn rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo gbogbo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,


Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀,


Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.


Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,


Gbogbo mààlúù tí wọ́n mú wá fún ọrẹ ẹbọ sísun jẹ́ mejila ati àgbò mejila, ọ̀dọ́ àgbò mejila ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Wọ́n tún mú òbúkọ mejila wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan