Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:85 - Yoruba Bible

85 ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

85 Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

85 Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:85
7 Iomraidhean Croise  

Mo ti sa gbogbo agbára mi láti tọ́jú ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) talẹnti wúrà kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé OLUWA, aadọta ọ̀kẹ́ (1,000,000) talẹnti fadaka, ati idẹ, ati irin tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè wọ̀n. Mo ti tọ́jú òkúta ati pákó pẹlu. O gbọdọ̀ wá kún un.


Mo ti pèsè ẹgbẹẹdogun (3,000) ìwọ̀n talẹnti wúrà dáradára láti ilẹ̀ Ofiri, ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka tí a ti yọ́, láti fi bo gbogbo ògiri tẹmpili náà,


Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin.


Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,


Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli.


Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan