Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:23 - Yoruba Bible

23 Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Wọ́n jẹ́ ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Ṣuari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:23
8 Iomraidhean Croise  

Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́.


“Mo ti rú ẹbọ alaafia, mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí.


Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Isakari.


Kí ẹ̀yà Isakari pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Juda; Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí wọn.


òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


Ní ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olórí ẹ̀yà Sebuluni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.


Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti arakunrin wa, àwa ni à ń kọ ìwé yìí–


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan