Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:13 - Yoruba Bible

13 Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:13
23 Iomraidhean Croise  

Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn.


Bàbà dídán ni Huramu fi ṣe àwọn ìkòkò ati ọkọ́ ati àwokòtò ati gbogbo ohun èlò inú ilé OLUWA tí ó ṣe fún Solomoni ọba.


Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun.


Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù.


Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.


Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù.


Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.


Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí.


“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀.


“Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan.


Fún ọkunrin tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún sí ọgọta ọdún, yóo san aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ìwọ̀n ṣekeli ibi mímọ́ ni kí wọ́n fi wọn owó náà.


Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ.


ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ;


pẹlu ìdámẹ́wàá ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró tí a gún pọ̀.


Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.


Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.


Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá.


Àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;


Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.


Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀.


Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan