Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:10 - Yoruba Bible

10 Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:10
12 Iomraidhean Croise  

Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́.


Solomoni ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) mààlúù ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rúbọ. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn eniyan náà ṣe ya ilé Ọlọrun sí mímọ́.


Wọ́n fi ọjọ́ meje ṣe ìyàsímímọ́ pẹpẹ, wọ́n sì fi ọjọ́ meje ṣe àjọyọ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n pe àpéjọ mímọ́.


Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.


Wọ́n ṣe ìrúbọ pataki ní ọjọ́ náà, wọ́n sì yọ̀, nítorí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá, àwọn obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wọn náà yọ̀ pẹlu. Àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn réré sì gbúròó igbe ayọ̀ ní Jerusalẹmu.


N óo yìn ọ́, OLUWA, nítorí pé o ti yọ mí jáde; o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.


Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀,


OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.”


Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,


Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i.


“Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan