Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:9 - Yoruba Bible

9 “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:9
11 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ tí ó bá lọ sí ibi mímọ́, tí ó bá lọ sinu gbọ̀ngàn inú láti ṣiṣẹ́ iranṣẹ ní ibi mímọ́, ó gbọdọ̀ rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.


Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́.


Nasiri náà yóo fá irun orí rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì fi irun náà sinu iná tí ó wà lábẹ́ ẹbọ alaafia.


Yóo jẹ́ mímọ́ fún OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.


Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.


Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu,


Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan