Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:5 - Yoruba Bible

5 “Kò gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ tabi kí ó fá a títí tí ọjọ́ tí ó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́, kí ó sì jẹ́ kí ìdì irun orí rẹ̀ máa dàgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:5
9 Iomraidhean Croise  

“Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni.


Ní gbogbo ìgbà tí ó bá jẹ́ Nasiri, kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí a fi èso àjàrà ṣe, kì báà jẹ́ kóró tabi èèpo rẹ̀.


Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.


Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”


Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”


Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀.


Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan