Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:3 - Yoruba Bible

3 yóo jáwọ́ kúrò ninu ọtí waini mímu, ati ọtí líle. Kò gbọdọ̀ mu ọtí kíkan tí a fi waini tabi ọtí líle ṣe. Kò gbọdọ̀ mu ọtí èso àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ jẹ èso àjàrà tútù tabi gbígbẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:3
15 Iomraidhean Croise  

“Nígbà tí o bá ń wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ, ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ẹ kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ má baà kú; èyí yóo jẹ́ ìlànà títí ayé fún arọmọdọmọ yín.


Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́.


Ní gbogbo ìgbà tí ó bá jẹ́ Nasiri, kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí a fi èso àjàrà ṣe, kì báà jẹ́ kóró tabi èèpo rẹ̀.


Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀;


“Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran.


Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.


Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú.


Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo.


Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.


Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.”


Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan