Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:12 - Yoruba Bible

12 Lẹ́yìn náà ni ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kì yóo ka àwọn ọjọ́ tí ó ti lò ṣáájú nítorí pé ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti bàjẹ́ nítorí pé ó fi ara kan òkú. Yóo sì mú ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan tọ alufaa wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:12
12 Iomraidhean Croise  

Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan.


“Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.


Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.


kí ó sì mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ OLUWA fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Kí ó mú abo ọ̀dọ́ aguntan, tabi ti ewúrẹ́ wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.


“Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.


Alufaa yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi ikeji rú ẹbọ sísun láti ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa fífi ara kan òkú; yóo sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà.


“Èyí ni yóo jẹ́ òfin fún Nasiri: Nígbà tí ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé, yóo wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ


Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.


Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un.


Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin.


Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan