Numeri 6:11 - Yoruba Bible11 Alufaa yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi ikeji rú ẹbọ sísun láti ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa fífi ara kan òkú; yóo sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ11 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an. Faic an caibideil |