Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:10 - Yoruba Bible

10 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:10
11 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́.


“Bí ó bá jẹ́ pé ẹyẹ ni eniyan bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, kí ó mú àdàbà tabi ọmọ ẹyẹlé wá.


“Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, kì báà ṣe fún ọmọkunrin tabi fún ọmọbinrin, yóo mú ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan wá sí ọ̀dọ̀ alufaa ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ fún ẹbọ sísun, kí ó sì mú yálà ọmọ ẹyẹlé tabi àdàbà wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.


Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji, kí ó wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó sì kó wọn fún alufaa.


Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.


ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan