Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:8 - Yoruba Bible

8 Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:8
8 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.


Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.


tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.


“Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà.


olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀.


Àwọn alufaa ni wọ́n ni gbogbo àwọn ohun ìrúbọ, ati gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá sọ́dọ̀ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan