Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:7 - Yoruba Bible

7 olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:7
14 Iomraidhean Croise  

Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ. Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,” o sì dáríjì mí.


Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.


“Ṣugbọn bí wọn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, nípa ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí mi, ati lílòdì tí wọ́n lòdì sí mi,


tí mo fi kẹ̀yìn sí wọn, tí mo fi mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; bí ọkàn wọn tí ó ti yigbì tẹ́lẹ̀ bá rọ̀, tí wọ́n bá sì ṣe àtúnṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn,


“Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni.


Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.


“Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí a ti dárúkọ wọnyi, kí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá,


“Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà.


Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.


Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.”


Joṣua wí fún Akani pé, “Ọmọ mi, fi ògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí o sì yìn ín. Jẹ́wọ́ ohun tí o ṣe, má fi pamọ́ fún mi.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan