Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:3 - Yoruba Bible

3 Ẹ kó wọn sí ẹ̀yìn odi kí wọn má baà sọ ibùdó yín di aláìmọ́ nítorí pé mò ń gbé inú rẹ̀ pẹlu àwọn eniyan mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:3
23 Iomraidhean Croise  

Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí.


Ó gun òkè gíga, ó kó àwọn eniyan nígbèkùn; ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan, ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá. OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.


kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn.


N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.


Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni, ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni, nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó wà láàrin yín.”


Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.


“Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.”


Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?”


Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”


Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.”


Àwọn ọmọ Israẹli sì yọ wọ́n kúrò láàrin wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.


Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.


“Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀.


Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa.


Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un.


Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.


Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan