Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:5 - Yoruba Bible

5 “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:5
23 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose.


Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”


Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ti àlàárì ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ ìbòjú fún ibi mímọ́ jùlọ, ó sì ya àwòrán kerubu sí i lára.


Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára.


Kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí tí òfin mẹ́wàá wà ninu rẹ̀ sinu àgọ́ náà, kí o sì ta aṣọ ìbòjú dí i.


Lẹ́yìn náà, gbé pẹpẹ wúrà turari siwaju àpótí ẹ̀rí náà, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.


Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.


“Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú.


Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn.


Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú.


Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ ninu Àgọ́ Àjọ.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.


Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán.


Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.


nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀.


Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà.


Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan