Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:25 - Yoruba Bible

25 Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:25
8 Iomraidhean Croise  

“Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà.


“Lẹ́yìn náà, fi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, ati awọ ewúrẹ́ tí a ṣe dáradára, ṣe ìbòrí keji fún àgọ́ náà.


Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí:


Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan