Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:23 - Yoruba Bible

23 ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:23
18 Iomraidhean Croise  

Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.


Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí:


Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000).


“Ka iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn:


Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí:


Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.


Nígbà tí wọ́n bá di ẹni aadọta ọdún, iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Àjọ yóo dópin. Wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ níbẹ̀ mọ́,


Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?


À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì.


Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe.


Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara.


Timoti ọmọ mi, ọ̀rọ̀ àṣẹ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wolii sọ nípa rẹ̀ tí mo fi yàn ọ́, pé kí o ja ìjà rere pẹlu agbára àṣẹ yìí.


Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan