Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:19 - Yoruba Bible

19 ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:19
6 Iomraidhean Croise  

Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú.


OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun.


OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.


Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú.


Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú.


“Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan