Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:16 - Yoruba Bible

16 “Eleasari ọmọ Aaroni Alufaa ni yóo ṣe ìtọ́jú òróró fìtílà, ati turari olóòórùn dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró ìyàsímímọ́, ati gbogbo Àgọ́ náà. Yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati àwọn ohun èlò ibẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:16
20 Iomraidhean Croise  

òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari,


Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé,


ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.”


Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é.


OLUWA sọ fún Mose pé,


“Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún àtùpà ilé mímọ́ mi, kí ó lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.


“Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́.


Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.


OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,


“Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


Bí ó ti yẹ kí eniyan máa rò nípa wa ni pé a jẹ́ iranṣẹ Kristi ati ìríjú àwọn nǹkan àṣírí Ọlọrun.


Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan,


Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa.


Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.


Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín.


Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan