Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:15 - Yoruba Bible

15 Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:15
26 Iomraidhean Croise  

Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn.


Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA.


Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà.


Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose.


Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”


Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”


Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á.


OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun.


Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e.


Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú.


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.


Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé.


Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú.


Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.


Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.


ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé.


Àwọn ìdílé Kohati kò gbọdọ̀ wọ inú ibi mímọ́ láti yọjú wo àwọn ohun mímọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá yọjú wò wọ́n yóo kú.”


Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.


Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.


Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un.


Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan