Numeri 4:14 - Yoruba Bible14 Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. Faic an caibideilBibeli Mimọ14 Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní14 Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. Faic an caibideil |