Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:12 - Yoruba Bible

12 Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:12
16 Iomraidhean Croise  

Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé.


Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá.


Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba.


Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA.


Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn.


Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà.


awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia;


Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.


ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn,


Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.


“Lẹ́yìn èyí, wọn óo da aṣọ aláwọ̀ aró bo pẹpẹ wúrà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò ó, wọn óo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.


Wọn óo kó eérú kúrò lórí pẹpẹ, wọn óo fi aṣọ elése àlùkò bò ó.


Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.


“Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.


“Wọn yóo fi aṣọ aláwọ̀ aró bo ọ̀pá fìtílà ati àwọn fìtílà rẹ̀ ati àwọn ohun tí à ń lò pẹlu rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò òróró.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan