Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:2 - Yoruba Bible

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:2
23 Iomraidhean Croise  

Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa.


N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!”


ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún, yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”


Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde.


OLUWA ní, “Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi, tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára, kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù, láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ, ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.


OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;


ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.


Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’


Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo.


Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ,


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.


Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.


Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan