Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 33:3 - Yoruba Bible

3 Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 33:3
10 Iomraidhean Croise  

Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ.


Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde, nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n.


Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao.


“Oṣù yìí ni yóo jẹ́ oṣù kinni ọdún fún yín.


Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.


Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu.


OLUWA mú ọkàn Farao, ọba Ijipti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń lọ tìgboyà-tìgboyà.


Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde. Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín, Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.


Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.


(Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.)


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan