Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:5 - Yoruba Bible

5 Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Tí a bá rí ojúrere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:5
11 Iomraidhean Croise  

Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú.


Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.”


Nígbà tí ó rí Ẹsita tí ó dúró ní ìta, inú rẹ̀ dùn sí i, ọba na ọ̀pá oyè tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí i, Ẹsita sì na ọwọ́, ó fi kan ṣóńṣó ọ̀pá náà.


Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀; nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi,


tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ.


Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni?


OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀.


Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀.


Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.”


Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan