Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:3 - Yoruba Bible

3 “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:3
22 Iomraidhean Croise  

O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani.


Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀, koríko ibẹ̀ gbẹ; àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.


OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé, “Nebo gbé nítorí yóo di ahoro! Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o; ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀;


ògo Moabu ti dópin! Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’ Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu; ogun yóo máa le yín kiri.


Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima, ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ! Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri, apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.


“Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ.


Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni, wọn kò lágbára mọ́, nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboni ahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba; iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun,


nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká.


Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni, àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná; wọ́n run ìlú Ari ní Moabu, ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni.


Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run, láti Heṣiboni dé Diboni, láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”


Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò.


Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn,


wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní,


Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni;


Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà;


Heṣiboni, ati Jaseri pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.


Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan