Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilẹ̀ Jaseri àti Gileadi dára fún ohun ọ̀sìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:1
30 Iomraidhean Croise  

Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ.


Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.


Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.”


Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni.


Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri.


Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni.


Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.


Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù.


OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé, “Bíi Gileadi ni o dára lójú mi, ati bí orí òkè Lẹbanoni. Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀; o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé.


Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima, ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ! Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri, apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.


N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.


Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni? Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀? Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?


OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.


Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò.


wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní,


“Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi,


“Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,


ati Atirotu Ṣofani, Jaseri, Jogibeha,


Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn, nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà, ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà, àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́, wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.”


Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba;


Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ sí ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, àwọn tí wọ́n rán ni Finehasi, ọmọ Eleasari, alufaa,


Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ọmọ Israẹli yòókù sílẹ̀ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì pada lọ sí ilẹ̀ Gileadi tí í ṣe ilẹ̀ tiwọn tí wọ́n pín fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.


Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé.


Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan? Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì, ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan