Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:3 - Yoruba Bible

3 Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:3
10 Iomraidhean Croise  

Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli.


Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun, kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo.


pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí:


Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe.


ó gbọdọ̀ ṣe bí ó ti wí, àfi bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe.


“Nígbà tí ọkunrin tabi obinrin kan bá ṣe ìlérí láti di Nasiri, tí ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA,


àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà.


Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.”


Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan