Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:7 - Yoruba Bible

7 Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:7
13 Iomraidhean Croise  

Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí.


Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.


Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.


Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.”


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”


Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.


Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.


Lára ìdajì tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, mú ẹyọ kan ninu araadọta ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn; kí o sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA.”


kí Aaroni alufaa wá ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn OLÚWA.


Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan