Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:6 - Yoruba Bible

6 “Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:6
18 Iomraidhean Croise  

Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”


Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA.


Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.


Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,


Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jáfara, nítorí pé OLUWA ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀, ati láti sìn ín; láti jẹ́ iranṣẹ rẹ̀ ati láti máa sun turari sí i.”


Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose.


Nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni mo pàṣẹ yìí fun yín, kí majẹmu mi pẹlu Lefi má baà yẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!


OLUWA wí pé, “Mo ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ.


Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.


Ṣugbọn a kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan