Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:51 - Yoruba Bible

51 Mose fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ní owó ìràpadà náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

51 Mose si fi owo awọn ti a rapada fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:51
11 Iomraidhean Croise  

Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni.


“Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu.


Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.”


Kí o sì kó owó náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀.”


Owó tí ó gbà jẹ́ egbeje ìwọ̀n ṣekeli fadaka ó dín marundinlogoji (1,365), gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.


OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:


N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni.


Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ? Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi.


Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan