Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:3 - Yoruba Bible

3 Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:3
10 Iomraidhean Croise  

Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.


Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.


Kó àwọn ẹ̀wù mímọ́ náà wọ Aaroni, ta òróró sí i lórí, kí o sì yà á sí mímọ́ kí ó lè máa ṣe alufaa mi.


Ta òróró sí wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí o ti ta á sí baba wọn lórí, kí àwọn náà lè máa ṣe alufaa mi. Òróró tí o bá ta sí wọn lórí ni yóo sọ àwọn ati gbogbo ìran wọn di alufaa títí lae.”


Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́.


Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn.


Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn.


Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan