Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:25 - Yoruba Bible

25 Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:25
23 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.


Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.


Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.


Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn.


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


Nígbà tí wọ́n tú Àgọ́ Àjọ palẹ̀, àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari tí ó ru Àgọ́ Àjọ náà ṣí tẹ̀lé àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Juda.


Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn.


Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.


Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn.


Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.


Ẹ sọ fún Akipu pé kí ó má jáfara nípa iṣẹ́ tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Oluwa, kí ó ṣe é parí.


Timoti ọmọ mi, ọ̀rọ̀ àṣẹ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wolii sọ nípa rẹ̀ tí mo fi yàn ọ́, pé kí o ja ìjà rere pẹlu agbára àṣẹ yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan