Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:15 - Yoruba Bible

15 “Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 “Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:15
17 Iomraidhean Croise  

Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn.


Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.


“Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.


OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.


Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.


Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn,


Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari,


Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.


Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500).


Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.


Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaata lé igba (6,200).


Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273).


Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.


Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan