Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:10 - Yoruba Bible

10 Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:10
25 Iomraidhean Croise  

Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà.


Jeroboamu tún kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sí orí òkè káàkiri, ó sì yan àwọn eniyan ninu gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ìran ẹ̀yà Lefi, láti máa ṣiṣẹ́ alufaa.


àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn.


Ṣugbọn mo dá a lóhùn pé, “Ṣé irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ? Àbí irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ sinu tẹmpili kí ó lọ máa gbé ibẹ̀? N kò ní lọ.”


dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi.


Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀.


“Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn.


OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.


OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa.


OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ.


Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.


Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú.


Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”


OLUWA sọ fún Mose pé,


Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.


Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.


Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun.


Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un.


Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.


Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀.


Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan