Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 28:3 - Yoruba Bible

3 “Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 28:3
25 Iomraidhean Croise  

láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli.


Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́.


Lẹ́yìn náà, wọ́n rú àwọn ẹbọ wọnyi: ẹbọ àtìgbà-dégbà, ẹbọ oṣù titun, gbogbo ẹbọ ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati ti àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rú ẹbọ àtinúwá sí OLUWA.


Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀.


“Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).


Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀.


Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”


Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí.


“Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà.


OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta.


Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu.


Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ yìí, ẹ óo tún fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí OLUWA.


Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ.


Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.


Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi pẹlu ẹbọ ohun mímu wọn, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ojoojumọ.


Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́,


ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.”


pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.


Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.


Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.


Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.


Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan