Numeri 28:2 - Yoruba Bible2 pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 “Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’ Faic an caibideil |
Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”